15 Nitori ẹnyin kò tun gbà ẹmí ẹrú lati mã bẹ̀ru mọ́: ṣugbọn ẹnyin ti gbà ẹmí isọdọmọ, nipa eyi ti awa fi nke pé, Abba, Baba.
16 Ẹmí tikararẹ̀ li o mba ẹmí wa jẹrí pe, ọmọ Ọlọrun li awa iṣe:
17 Bi awa ba si jẹ ọmọ, njẹ ajogun li awa, ajogun Ọlọrun, ati ajumọ-jogun pẹlu Kristi; biobaṣepe awa bá a jìya, ki a si le ṣe wa logo pẹlu rẹ̀.
18 Nitori mo ṣíro rẹ̀ pe, ìya igba isisiyi kò yẹ lati fi ṣe akawe ogo ti a o fihàn ninu wa.
19 Nitori ifojusọ́na ti ẹda nduro dè ifihàn awọn ọmọ Ọlọrun.
20 Nitori a tẹri ẹda ba fun asan, ki iṣe ifẹ rẹ̀, ṣugbọn nitori ẹniti o tẹ ori rẹ̀ ba, ni ireti,
21 Nitori a ó sọ ẹda tikalarẹ di omnira kuro ninu ẹrú idibajẹ, si omnira ogo awọn ọmọ Ọlọrun.