Dáníẹ́lì 11:6-12 BMY

6 Lẹ́yìn ọdún púpọ̀ wọn yóò dá májẹ̀mú àlàáfíà, ọmọbìnrin ọba gúṣù yóò lọ sí ọ̀dọ̀ ọba àríwá láti bá a dá májẹ̀mú àlàáfíà, ṣùgbọ́n òun kì yóò lè di agbára apá a rẹ̀ mú, bẹ́ẹ̀ ni òun kì yóò lè dá dúró, ṣùgbọ́n a ó tẹrí i rẹ̀ ba àti àwọn tí ó mú un wá, àti ọmọ tí ó bí, àti ẹni tí ó ń mu lọ́kàn le ní gbogbo àkókò wọ̀nyí.

7 “Ọ̀kan lára àwọn ìdílé e rẹ̀, ọmọbìnrin ọba Gúṣù yóò dìde láti gba ipò o rẹ̀. Yóò sì kọ lu ogun ọba àríwá, yóò sì wọ́ odi alágbára; yóò bá wọn jà yóò sì borí.

8 Yóò gba òrìṣà wọn, ère dídá àti ohun èlò oníye lórí ti fàdákà àti ti wúrà, yóò sì kó wọn lọ sí Éjíbítì. Fún ọdún díẹ̀ yóò fi ọba àríwá lọ́rùn sílẹ̀.

9 Nigbà náà, ni ọba àríwá yóò gbógun ti ilẹ̀ ọba, Gúṣù, ṣùgbọ́n yóò padà sí orílẹ̀ èdè Òun fúnra rẹ̀

10 Àwọn ọmọ rẹ̀ yóò múra ogun wọn yóò kó ogun ńlá jọ, èyí tí a ó gbá lọ bí àgbàrá omi ńlá, yóò sì gbá a lọ títí dé ìlú olódi rẹ̀.

11 “Nígbà náà ni ọba Gúṣù yóò jáde pẹ̀lú ìbínú, yóò sì bá ọba àríwá jà, ẹni tí yóò kó ọmọ ogun púpọ̀ jọ, ṣùgbọ́n ọba Gúṣù yóò borí i wọn.

12 Nígbà tí a bá kó ogun náà lọ, ọba Gúṣù yóò kún fún agbára, yóò sì pa ẹgbẹgbẹ̀rún ní ìpakúpa ṣíbẹ̀ kì yóò ṣẹ́gun.