6 Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ̀ tí kò bá wólẹ̀, kí ó fi orí balẹ̀, kí a ju ẹni náà sínú iná ìléru.”
7 Nítorí náà, bí wọ́n ṣe gbọ́ ohùn ìwo, fèrè, dùùrù, ohun èlò orin olókùn, ìpè àti onírúurú orin, gbogbo ènìyàn, orílẹ̀ èdè, àti èdè gbogbo wólẹ̀, wọ́n sì fi orí balẹ̀ fún ère wúrà tí ọba Nebukadinéṣárì gbé kalẹ̀.
8 Ní àsìkò yìí ni àwọn awòràwọ̀ bọ́ síwájú, wọ́n sì fi ẹ̀sùn kan àwọn ará a Júdà.
9 Wọ́n sọ fún ọba Nebukadinṣárì pé, “Kí ọba kí ó pẹ́.
10 Ìwọ ọba ti pàṣẹ pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá ti gbọ́ ohùn ìwo, fèrè, dùùrù, ohun èlò orin olókùn, ìpè àti onírúurú orin gbọdọ̀ wólẹ̀ kí ó fi orí balẹ̀ fún ère wúrà
11 àti ẹnikẹ́ni tí kò bá wólẹ̀, kí ó forí balẹ̀, a ó sọ irú ẹni bẹ́ẹ̀ sínú iná ìléru.
12 Ṣùgbọ́n àwọn ará a Júdà kan wà, àwọn tí a yàn láti ṣe olórí agèégbè ìjọba Bábílónì: Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dinígò, wọ́n ò ka ìwọ ọba sí. Wọn kò sin òrìṣà rẹ, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò fi orí balẹ̀ fún ère wúrà tí ìwọ gbé kalẹ̀.”