2 Ó jẹ́ ìdùnnú fún mi láti fi iṣẹ́ àmì àti ìyanu tí Ọlọ́run Ọ̀gá Ògo ti ṣe fún mi hàn.
3 Báwo ni àmì rẹ̀ ti tóbi tó,Báwo ni ìyanu rẹ̀ ṣe pọ̀ tó!Ìjọba rẹ̀, ìjọba títí ayé ni;ilẹ̀ ọba rẹ̀ láti ìran dé ìran ni.
4 Èmi Nebukadinéṣárì wà ní ààfin mi, pẹ̀lú ìtẹ́lọ́rùn àti àlàáfíà.
5 Mo lá àlá kan èyí tí ó bà mí lẹ́rù. Nígbà tí mo wà lórí ibùṣùn mi, ìran tí ó jáde lọ́kàn mi dẹ́rù bà mí.
6 Nígbà náà, ni mo pàṣẹ pé kí a mú gbogbo àwọn amòye Bábílónì wá, kí wọn wá sọ ìtumọ̀ àlá náà fún mi.
7 Nígbà tí àwọn onídán, àwọn apògèdè, àwọn awòràwọ̀ àti àwọn aláfọ̀ṣẹ wá, mo sọ àlá náà fún wọn, ṣùgbọ́n wọn kò le è sọ ìtúmọ̀ àlá náà fún mi.
8 Ní ìkẹyìn Dáníẹ́lì wá síwájú mi, mo sì sọ àlá náà fún (ẹni tí à ń pè ní Beliteṣáṣárì gẹ́gẹ́ bí orúkọ òrìṣà mi àti pé ẹ̀mí àwọn Ọlọ́run mímọ́ wà nínú un rẹ̀.)