25 A ó lé ọ jáde kúrò láàrin ènìyàn, ìwọ yóò sì máa gbé láàrin ẹranko búburú: ìwọ yóò jẹ koríko bí i màlúù, ìrì ọ̀run yóò sì sẹ̀ sára rẹ. Ìgbà méje yóò sì kọjá lórí ì rẹ, títí ìwọ yóò fi mọ̀ wí pé Ọ̀gá Ògo ń jọba lórí ìjọba ènìyàn, ó sì ń fi fún ẹni tí ó bá wù ú.
26 Bí wọ́n ṣe pàṣẹ pé kí wọn fi kùkùté àti gbòǹgbò igi náà sílẹ̀, èyí túmọ̀ sí wí pé a ó dá ìjọba rẹ padà fún ọ lẹ́yìn ìgbà tí o bá ti mọ̀ wí pé, Ọ̀run jọba.
27 Nítorí náà ọba, jẹ́ kí ìmọ̀ràn mi jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún ọ, kọ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ sílẹ̀ kí o sì ṣe rere, àti ìwà búburú rẹ nípa ṣíṣe àánú fún àwọn talákà. Ó lè jẹ́ pé nígbà náà ni ìwọ yóò ṣe rere.”
28 Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ṣẹlẹ̀ sí Nebukadinéṣárì ọba.
29 Lẹ́yìn oṣù kejìla, bí ọba ṣe ń rìn káàkiri lórí òrùlé ààfin ìjọba Bábílónì,
30 Ó sọ pé, “Èyí ha kọ́ ni Bábílónì ńlá tí mo kọ́ gẹ́gẹ́ bí ilé ọba, nípa agbára à mi àti fún ògo ọláńlá à mi?”
31 Bí ọba ṣe ń sọ ọ̀rọ̀ náà lọ́wọ́ ohùn kan wá láti ọ̀run “Ìwọ Nebukadinéṣárì ọba, ìwọ ni a ti pàṣẹ nípa rẹ̀, a ti gba ìjọba à rẹ kúrò ní ọwọ́ ọ̀ rẹ.