Dáníẹ́lì 4:29-35 BMY

29 Lẹ́yìn oṣù kejìla, bí ọba ṣe ń rìn káàkiri lórí òrùlé ààfin ìjọba Bábílónì,

30 Ó sọ pé, “Èyí ha kọ́ ni Bábílónì ńlá tí mo kọ́ gẹ́gẹ́ bí ilé ọba, nípa agbára à mi àti fún ògo ọláńlá à mi?”

31 Bí ọba ṣe ń sọ ọ̀rọ̀ náà lọ́wọ́ ohùn kan wá láti ọ̀run “Ìwọ Nebukadinéṣárì ọba, ìwọ ni a ti pàṣẹ nípa rẹ̀, a ti gba ìjọba à rẹ kúrò ní ọwọ́ ọ̀ rẹ.

32 A ó lé ọ kúrò láàrin àwọn ènìyàn, ìwọ yóò sì lọ máa gbé àárin àwọn ẹranko igbó; ìwọ yóò jẹ koríko bí i màlúù, ìgbà méje yóò kọjá lórí i rẹ títí ìwọ yóò fi mọ̀ wí pé, Ọ̀gá Ògo jọba lórí ìjọba ènìyàn àti pé ó ń fi fún ẹni tí ó bá wù ú.”

33 Lẹ́ṣẹ̀kẹṣẹ̀ ni ohun tí a sọ nípa Nebukadinéṣárì ṣẹlẹ̀ sí i. A lé e kúrò láàrin ènìyàn, ó sì ń jẹ koríko bí i màlúù, ìrì ọ̀run sì ń ṣẹ̀ sí ara rẹ̀, títí irun orí i rẹ̀ fi gùn bí i ti ìyẹ́ ẹyẹ idì, tí èékánná rẹ̀ sì dàbí i ti ẹyẹ.

34 Ní òpin ìgbà náà, Èmi, Nebukadinéṣárì gbé ojú ù mi sókè sí ọ̀run, iyè mi sì sọjí. Mo fi ọpẹ́ fún Ọ̀ga Ògo; mo fi ọlá àti ògo fún ẹni tí ó wà láéláé.Ìjọba rẹ̀ ìjọba títí ayé niìjọba rẹ̀ wà láti ìran dé ìran

35 Gbogbo àwọn ènìyàn ayéni a kà sí asán.Ó ń ṣe bí ó ti wù ú,pẹ̀lú àwọn ogun ọ̀run,àti gbogbo àwọn ènìyàn ayétí kò sì sí ẹnì kankan tí ó lè dí i lọ́wọ́tàbí sọ fún un wí pé: “Kí ni ìwọ ń ṣe?”