Dáníẹ́lì 5:2-8 BMY

2 Bí Beliṣáṣárì ṣe ń mu wáìnì, ó pàṣẹ pé kí wọn kó kọ́ọ̀bù wúrà àti ti fàdákà wá, èyí tí Nebukadinéṣárì bàbá rẹ̀ kó wá láti inú tẹ́ḿpìlì ní Jérúsálẹ́mù, kí ọba àti àwọn ọlọ́lá a rẹ̀, àwọn ìyàwó àti àwọn àlè rẹ̀ kí ó ba à le fi mu wáìnì.

3 Wọ́n sì kó kọ́ọ̀bù wúrà àti fàdákà àti fàdákà èyí tí wọ́n kó jáde láti inú tẹ́ḿpìlì, ilé Ọlọ́run ní Jérúsálẹ́mù, ọba àti àwọn ìjòyè rẹ̀, àwọn ìyàwó àti àwọn àlè rẹ̀, sì fi mu wáìnì.

4 Bí wọ́n ṣe ń mu wáìnì bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń yin òrìṣà wúrà àti fàdákà, ti idẹ, irin, igi àti òkúta.

5 Lójijì, ìka ọwọ́ ènìyàn jáde wá, ó sì ń kọ̀wé sára ẹfun ògiri ní ẹ̀gbẹ́ ibi tí àtùpà ń dúró ní ààfin ọba. Ọba ń wo ọwọ́ náà bí ó ṣe ń kọ ọ́.

6 Ojú ọba sì yí padà, ẹ̀rù sì bàá, tó bẹ́ẹ̀ tí orúnkún ẹṣẹ̀ rẹ̀ méjèèjì rẹ̀ fi ń gbá ara wọn.

7 Ọba kígbe pé, kí wọn pe àwọn awòràwọ̀, àwọn onídán, àti àwọn aláfọ̀ṣẹ wá, ọba sì sọ fún àwọn amòye Bábílónì pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá lè ka àkọsílẹ̀ yìí kí ó sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀, ẹni náà ni a ó fi aṣọ eléṣèé àlùkò wọ̀ àti ẹ̀gbà wúrà ni a ó fi sí ọrùn un rẹ̀, òun ni yóò sì ṣe olórí kẹta ní ìjọba à mi.”

8 Nígbà náà ni gbogbo àwọn amòye ọba wọ ilé, ṣùgbọ́n, wọn kò le ka àkọsílẹ̀ náà tàbí sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún ọba.