17 ‘Àwọn ẹranko ńlá mẹ́rin yìí, ni ìjọba mẹ́rin tí yóò dìde ní ayé.
18 Ṣùgbọ́n, ẹni mímọ́ ti ọ̀gá ògo ni yóò gba ìjọba náà, yóò sì jogún un rẹ títí láé àti títí láéláé.’
19 “Nígbà náà, ni mo fẹ́ mọ ìtúmọ̀ òtítọ̀ ẹranko kẹrin, tí ó yàtọ̀ sí àwọn yóòkù, èyí tí ó dẹ́rù ba ni gidigidi, tí ó ní eyín irin àti èékánná idẹ, ẹranko tí ó ń run tí ó sì ń pajẹ, tí ó sì ń fi ẹsẹ̀ tẹ èyí tó kù mọ́lẹ̀.
20 Bẹ́ẹ̀ ni mo sì fẹ́ mọ̀ nípa ìwo mẹ́wàá orí i rẹ̀ àti nípa ìwo yóòkù tí ó jáde, nínú èyí tí mẹ́ta lára wọn ṣubú, ìwo tí ó ní ojú, tí ẹnu rẹ̀ ń sọ̀rọ̀ ìgbératga.
21 Bí mo ṣe ń wò, ìwo yìí ń bá àwọn ènìyàn mímọ́ jagun, ó sì borí i wọn,
22 títí ẹni ìgbàanì fi dé, ó sì ṣe ìdájọ́ ìdáláre fún àwọn ẹni mímọ́ ọ̀gá ògo, àsìkò náà sì dé nígbà tí àwọn ẹni mímọ́ náà jogun ìjọba.
23 “Ó ṣe àlàyé yìí fún mi pé: ‘Ẹranko kẹrin ni ìjọba kẹrin tí yóò wà ní ayé. Yóò yàtọ̀ sí gbogbo àwọn ìjọba yóòkù yóò sì pa gbogbo ayé run, yóò tẹ̀ẹ́ mọ́lẹ̀, yóò sì fọ́ ọ́ sí wẹ́wẹ́.