Dáníẹ́lì 7:9-15 BMY

9 “Bí mo ṣe ń wò,“a gbé ìtẹ́ ọba sí ìkàlẹ̀ẹni ìgbàanì orí ìtẹ́ rẹ̀Aṣọ rẹ̀ funfun bí ẹ̀gbọ̀n òwúIrun orí i rẹ̀ funfun bí òwúÌtẹ́ ọba rẹ̀ rí bí ọwọ́ iná.Àwọn kẹ̀kẹ́ rẹ ń jó bí i iná.

10 Odò iná ń ṣànó ń jáde ní iwájú u rẹ̀Àwọn ẹgbẹ̀rún lọ́ná ẹgbẹ̀rún ń foríbalẹ̀ fún un;Ọ̀nà ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá lọ́nà ẹgbẹ̀rúnmẹ́wàá sì dúró níwájú u rẹ̀.Àwọn onídàájọ́ jókòóa sì sí àwọn ìwé sílẹ̀.

11 “Nígbà náà ni mo bẹ̀rẹ̀ sí ní wò, nítorí àwọn ọ̀rọ̀ ìgbéraga tí ìwo náà ń sọ, mo wò títí a fi pa ẹranko náà, a sì pa á run, a sì jù ú sínú iná tí ń jó.

12 A sì gba ìjọba lọ́wọ́ àwọn ẹranko yóòkù, ṣùgbọ́n a fún wọn láàyè láti wà fún ìgbà díẹ̀.

13 “Nínú ìran mi ní òru mo wò, mo rí ẹnìkan tí ó dúró sí iwájú u mi, ó rí bí ọmọ ènìyàn, ó ń bọ̀ wá nínú àwọ̀ọsánmọ̀ ọ̀run, ó ń bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ ẹni ìgbàanì, a sì mú u wá sí iwájú rẹ̀.

14 A sì fi ìjọba, ògo àti agbára ilẹ̀ ọba fún un; gbogbo ènìyàn, orílẹ̀ èdè àti èdè gbogbo wọn wólẹ̀ fún un. Ìjọba rẹ̀, ìjọba ayérayé ni, èyí tí kò le è kọjá, ìjọba rẹ̀ kò sì le è díbàjẹ́ láéláé.

15 “Ọkàn èmi Dáníẹ́lì, dàrú, ìran tí ó wá sọ́kàn mi dẹ́rù bà mí.