17 Bí ó ṣe súnmọ́ ibi tí mo dúró sí, ẹ̀rù bàmí, mo sì dọ̀bálẹ̀. Ó ń sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, jẹ́ kí ó yé ọ pé ìran náà ń sọ nípa ìgbà ìkẹyìn ni.”
18 Bí ó ṣe ń bá mi sọ̀rọ̀, mo ti sùn lọ fọnfọn, bí mo ṣe da ojú bolẹ̀. Nígbà náà ni ó fi ọwọ́ kàn mí, ó sì gbé mi dúró lórí ẹsẹ̀ mi.
19 Ó sọ wí pé: “Èmi yóò sọ ohun tí yóò sẹlẹ̀ ní ìkẹyìn ní ìgbà ìbínú, nítorí ìran náà jẹ mọ́ àkókò ohun tí a yàn nígbà ìkẹyìn.
20 Àgbò oníwo méjì tí o rí, òun ni ó dúró gẹ́gẹ́ bí àwọn ọba Médíánì àti Páṣíà.
21 Òbúkọ onírun náà ni ọba Gíríkì, ìwo ńlá ti ó wà láàrin ojú u rẹ̀ ni ọba àkọ́kọ́.
22 Ìwo mẹ́rin ti ó dípo ọ̀kan tí ó kán dúró, èyí dúró gẹ́gẹ́ bí ìjọba mẹ́rin tí ó dìde láti orílẹ̀ èdè e rẹ̀ ṣùgbọ́n wọn kò ní ní irú agbára kan náà.
23 “Ní ìgbà ìkẹyìn ìjọba wọn, nígbà tí ìwà búburú àwọn ọlọ̀tẹ̀ bá burú gidigidi ọba tí ojú u rẹ̀ le koko, balógun rìkísí yóò dìde.