1 Ìwọ̀nyí ni àwọn orúkọ ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n bá Jákọ́bù lọ sí Éjíbítì, ẹnìkọ̀ọ̀kan pẹ̀lú ìdílé rẹ̀:
2 Rúbẹ́nì, Símónì, Léfì àti Júdà,
3 Ísákárì, Ṣébúlúnì àti Bẹ́ńjámínì,
4 Dánì àti Náfítalì, Gádì àti Ásérì.
5 Àwọn ìran Jákọ́bù sì jẹ́ àádọ́rin ní àpapọ̀; Jóṣẹ́fù sì ti wà ní Éjíbítì.
6 Wáyìí o, Jóṣẹ́fù àti gbogbo àwọn arákùnrin rẹ̀ àti gbogbo ìran náà kú,