1 Olúwa sọ fún Mósè pé,
2 “Ẹ ya àwọn àkọ́bí yín ọkùnrin ṣọ́tọ̀ fún mi. Èyí ti ó bá jẹ́ àkọ́bí láàrin àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ́ tèmi, ìbáà ṣe ènìyàn tàbí ẹranko.”
3 Nígbà náà ni Mósè sọ fún àwọn ènìyàn náà pé, “Ẹ rántí ọjọ́ òní, ọjọ́ ti ẹ jáde kúrò ni ilẹ́ Éjíbítì, kúrò ní ilẹ̀ tí ẹ̀yin ti ń ṣe ẹrú, nítorí Olúwa mú un yín jáde kúrò ni inú rẹ̀ pẹ̀lú ọwọ́ agbára. Ẹ má se jẹ ohunkóhun tí ó ni ìwúkàrà nínú.
4 Òní, ní oṣù Ábíbù (oṣù kẹta ọdún tiwa) lónìí ẹ̀yin ń jáde kúrò ní Éjíbítì.
5 Ní ìgbà tí Ọlọ́run mú un yín jáde wá sí ilẹ̀ ẹ Kénánì, Hítì, Ámórì, Hífì àti ilẹ̀ àwọn Jébúsì; ilẹ̀ tí ó ti ṣe ìlérí láti fi fún àwọn baba ńlá yín, ilẹ̀ tí ń sàn fún wàrà àti oyin, ẹ ni láti pa ìsìn yìí mọ́ ní oṣù yìí.
6 Fún ọjọ́ méje ni ìwọ yóò fi jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà nínú àti pé ní ọjọ́ keje ni àjọ yóò wà fún Olúwa.
7 Kí ẹ̀yin ó jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà fún ọjọ́ méje yìí; kó má ṣe sí ohunkóhun tí a fi ìwúkàrà ṣe ní sàkání yín.