16 Ó sì ṣe, àlùfáà Mídíánì kan ni àwọn ọmọbìnrin méje, wọn sì wá láti pọn omi kún ọpọ́n ìmumi fún ẹran ọ̀sìn baba wọn.
17 Àwọn darandaran kán wá, wọ́n sì lé wọn sẹ́yìn, ṣùgbọ́n Mósè dìde láti gbà wọ́n sílẹ̀ àti láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti fún ẹran wọn ní omi.
18 Nígbà ti àwọn ọmọbìnrin náà padà dé ọ̀dọ̀ Rúẹ́lì baba wọn, ó béèrè lọ́wọ́ wọn pé “Èéṣe tí ẹ̀yin fi tètè dé ni òní?”
19 Wọ́n dá a lóhùn pé, “Ará Éjíbítì kan ni ó gbà wá sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn darandaran, ó tilẹ̀ ràn wá lọ́wọ́ láti fa omi àti láti fún agbo ẹran ní omi.”
20 Ó sọ fún àwọn ọmọbìnrin rẹ̀, “Níbo ni ó wà? Èéṣe ti ẹ fi fi ọkùnrin náà sílẹ̀? Ẹ pè é wá jẹun.”
21 Mósè gbà láti dúró lọ́dọ̀ ọkùnrin náà, ẹni tí o fi Sípórà, ọmọbìnrin rẹ̀ fún Mósè láti fi ṣe aya.
22 Ó sì bí ọmọkùnrin kan tí ó pe orúkọ rẹ̀ ní Gésómù, ó wí pé “Èmi ń ṣe àtìpó ní ilẹ̀ àjèjì.”