1 Olúwa sì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí pé:
2 “Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín, ẹni tí ó mú un yín jáde ni ilẹ̀ Éjíbítì, jáde ni oko ẹrú.
3 “Ìwọ kò gbọdọ̀ ní Ọlọ́run mìíràn pẹ̀lú mi.
4 “Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ère fún ara rẹ ní àwòrán ohun kóhun tí ń bẹ ní òkè ọ̀run tàbí tí ń bẹ ní ayé, tàbí tí ń bẹ ní ìṣàlẹ̀ omi.