4 “Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ère fún ara rẹ ní àwòrán ohun kóhun tí ń bẹ ní òkè ọ̀run tàbí tí ń bẹ ní ayé, tàbí tí ń bẹ ní ìṣàlẹ̀ omi.
5 Ìwọ kò gbọdọ̀ tẹ orí ara rẹ ba fún wọn, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ sìn wọ́n; nítorí Èmi Olúwa Ọlọ́run rẹ, Ọlọ́run owú ni mí, tí ń bẹ ẹ̀sẹ̀ baba wò lára ọmọ láti ìran kìn-ín-ní títí dé ẹ̀kẹrin nínú àwọn tí ó kórìíra mi.
6 Ṣùgbọ́n mo ń fi ìfẹ́ hàn sí ẹgbẹ̀rún ìran nínú àwọn tí ó fẹ́ mi tí wọ́n sì ń pa òfin mi mọ́.
7 “Ìwọ kò gbọdọ̀ pe orúkọ Olúwa Ọlọ́run rẹ ní asán, nítorí Olúwa kì yóò ka àwọn tí ó ń pe orúkọ rẹ̀ ní asán bí aláìlẹ́ṣẹ̀ ní ọ̀run.
8 “Rántí ọjọ́ ìsinmi kí o sì yà á sí mímọ́.
9 Ọjọ́ mẹ́fà ni ìwọ yóò fi ṣiṣẹ́, kí ìwọ kí ó ṣe gbogbo iṣẹ́ rẹ,
10 Ṣùgbọ́n ọjọ́ keje ni ọjọ́ ìsinmi Olúwa Ọlọ́run rẹ. Nínú rẹ̀ ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́kiṣẹ́ kan: ìwọ, àti ọmọ rẹ ọkunrìn àti ọmọ rẹ obìnrin, ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ ọkùnrin tàbí ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ obìnrin, tàbí ẹran ọ̀sìn rẹ, àti àlejò rẹ tó wà ní nínú ibodè rẹ.