15 Nígbà tí Mósè gun orí òkè lọ, ìkúúkùù bo orí òkè náà.
16 Ògo Olúwa sì wà ní orí òkè Ṣí náì. Ìkùùkuu bo orí òkè náà fún ọjọ́ mẹ́fà, ni ọjọ́ keje ni Olúwa kọ sí Mósè láti inú ìkùùkuu náà wá.
17 Ni ojú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ògo Olúwa náà dà bí iná ajónirun ni orí òkè.
18 Nígbà náà ni Mósè wọ inú ìkùùkuu náà bí ó ti ń lọ ní orí òkè. Ó sì wà ni orí òkè náà ni ogójì ọ̀sán àti ogójì òru.