28 pẹpẹ ẹbọ sísun àti gbogbo ohun èlò rẹ̀, àti agbada pẹ̀lú ẹṣẹ̀ rẹ̀.
29 Ìwọ yóò sì sọ wọ́n di mímọ́, nítorí kí wọn lè jẹ́ mímọ́ jùlọ, àti ohunkóhun tí ó bá fí ọwọ́ kàn wọn yóò di mímọ́.
30 “Ìwọ yóò sì ta òróró sí orí Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀, ìwọ yóò sì sọ wọ́n di mímọ́, nítorí kí wọn lè sìn mí bí àlùfáà.
31 Ìwọ yóò sì sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Èyí ni yóò ṣe òróró mímọ́ ìtasórí mi fún ìrandíran tó ń bọ̀.
32 Má se dà á sí ara ènìyàn kí o má sì ṣe ṣe òróró kankan ni irú rẹ̀. Mímọ́ ni, ẹ̀yín sì gbọdọ̀ kà á sí mímọ́.
33 Ẹnikẹ́ni tí ó bá po irú rẹ̀, tàbí ẹnikẹ́ni tí ó bá fi sára ẹnìkankan yàtọ̀ sí àlùfáà, a ó gé e kúrò nínú àwọn ènìyàn rẹ̀.’ ”
34 Olúwa sọ fún Mósè pé, “Mú tùràrí olóòórùn dídùn sọ́dọ̀ rẹ, óníkà, àti gálíbánúmù àti kìkì tùràrí dáradára, iye kan ni gbogbo rẹ,