3 Ẹ gòkè lọ sí ilẹ̀ tó ń sán fún wàrà àti oyin. Ṣùgbọ́n èmi kò ní lọ pẹ̀lú yín, nítorí ènìyàn ọlọ́rùn líle ni ẹ̀yin, kí èmi má ba à run yín ní ọ̀nà.”
4 Nígbà tí àwọn ènìyàn náà gbọ́ ọ̀rọ̀ ìparun wọ̀nyí, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sì ní kùn, ẹnìkankan kò sì le è wọ ohun ọ̀sọ́ rẹ̀.
5 Nítorí Olúwa ti wí fún Mósè pé, “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Ènìyàn ọlọ́rùn líle ní ẹ̀yin, bí èmi bá lè wa sí àárin yín ni ìsẹ́jú kan, èmi lè pa yín run. Ní sinsin yìí, bọ́ ohun ọ̀sọ́ rẹ kúrò, èmi yóò sì gbèrò ohun tí èmi yóò se pẹ̀lú rẹ.’ ”
6 Bẹ́ẹ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bọ́ ohun ọ̀ṣọ́ wọn kúrò lára wọn ní òkè Hórébù.
7 Mósè máa ń gbé àgọ́ náà, ó sì pa á sí ìta ibùdó, ó jìnnà díẹ̀ sí ibùdó, ó pè é ni “Àgọ́ àjọ.” Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń bèrè Olúwa yóò lọ sí ibi àgọ́ àjọ náà ní ìta ibùdó.
8 Nígbàkúgbà tí Mósè bá jáde lọ sí ibi àgọ́, gbogbo ènìyàn á dìde, wọ́n á sì dúró sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ wọn, wọn yóò máa wo Mósè títí yóò fi wọ inú àgọ́ náà.
9 Bí Mósè ṣe wọ inú àgọ́ náà, ọ̀wọ̀n àwọ̀ọsánmọ̀ yóò sọ̀kalẹ̀, yóò sì dúró sí ẹnu ọnà, nígbà tí Olúwa ń sọ̀rọ̀ pẹ̀lú Mósè.