35 Wọ́n ṣe aṣọ títa ti aṣọ aláró, ti elésèé àlùkò, ti òdòdó àti ti ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára, wọ́n ṣe kérúbù si pẹ̀lú ọgbọ́n oníṣẹ́ ọnà.
36 Wọ́n sì ṣe òpó igi kasíá mẹ́rin fún-un wọ́n sì bò wọ́n pẹ̀lú wúrà. Wọ́n sì ṣe àwọn ìkọ́ wúrà fún wọn, wọ́n sì gba ihò ìtẹ̀bọ̀ fàdákà mẹ́rin wọn.
37 Fún ẹnu ọ̀nà Àgọ́ náà wọ́n ṣe aṣọ títa ti aṣọ aláró, ti elésèé àlùkù, ti òdòdò àti ti ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára iṣẹ́ abẹ́rẹ́;
38 wọ́n sì ṣe òpó márùn-ún pẹ̀lú ìkọ́ wọn. Wọ́n bo orí àwọn òpó náà àti ìgbànú wọn pẹ̀lú wúrà, wọn sì ṣe ihò ìtẹ̀bọ̀ márùn-ún wọn ní idẹ.