15 Ta òróró sí wọn ní orí gẹ́gẹ́ bí o ti ta òróró sí baba wọn ńi orí, nítorí kì wọn lè máa sìn mi bí àlùfáà. Ìtasórí wọn yóò jẹ́ iṣẹ́ àlùfáà ti yóò máa lò fún gbogbo ìrandíran tó ń bọ̀.”
16 Mósè ṣe ohun gbogbo gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún-un.
17 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gbé Àgọ́ náà ró ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kìn-ìn-ní ní ọdún kejì.
18 Nígbà tí Mósè gbé Àgọ́ náà ró ó fi ihò ìtẹ̀bọ̀ sí ààyè rẹ̀, ó to pákó rẹ̀, ó fi ọ̀pá rẹ̀ bọ̀ ọ́, ó sì gbé àwọn òpó rẹ̀ ró.
19 Ó na aṣọ àgọ́ náà sórí Àgọ́, ó sì fi ìbòrí bo orí Àgọ́ náà, bí Olúwa ṣe pàṣẹ fún un.
20 Ó mu ẹ̀rí, ó sì fi sínú àpótí, ó so àwọn òpó mọ́ àpótí náà, ó sì fi àánú bo orí rẹ.
21 Ó sì gbé àpótí náà wá sínú àgọ́; ó sì sọ aṣọ títa, ó sì ta á bo àpótí ẹ̀rí, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún-un.