20 Ó mu ẹ̀rí, ó sì fi sínú àpótí, ó so àwọn òpó mọ́ àpótí náà, ó sì fi àánú bo orí rẹ.
21 Ó sì gbé àpótí náà wá sínú àgọ́; ó sì sọ aṣọ títa, ó sì ta á bo àpótí ẹ̀rí, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún-un.
22 Mósè gbé tábìlì sínú àgọ́ àjọ sí ìhà àríwá àgọ́ náà lẹ́yìn aṣọ títa,
23 ó sì to àkàrà sórí rẹ̀ níwájú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún-un.
24 Ó gbé ọ̀pá fìtílà sínú àgọ́ àjọ ní òkánkán tábìlì ní ìhà gúsù Àgọ́ náà.
25 Ó sì tan àwọn fítìlà náà níwájú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún-un.
26 Mósè gbé pẹpẹ wúrà sínú Àgọ́ àjọ níwájú aṣọ títa