1 Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mósè pé, “Lọ sọ fún Fáráò, ‘Èyí ni Olúwa Ọlọ́run àwọn Hébérù sọ: “Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mi kí ó lọ, kí wọn bá à lè sìn mí.”
2 Bí ìwọ bá kọ̀ láti jẹ́ kí wọn ó lọ, tí ó sì dá wọn dúró.
3 Ọwọ́ Olúwa yóò mú àrùn búburú wá sí ara ẹran ọ̀sìn nínú oko, sí ara ẹsin, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, rànkunmí, màlúù, àgùntàn àti ewúrẹ́ yín.
4 Ṣùgbọ́n Olúwa yóò pààlà sí àárin ẹran ọ̀sìn tí ó jẹ́ ti Ísírẹ́lì àti ti àwọn ara Éjíbítì tí yóò fi jẹ́ pé kò sí ẹran ọ̀sìn ti ó jẹ́ ti ará Ísírẹ́lì tí yóò kú.’ ”
5 Olúwa sì dá àkókò kan wí pé, “Ní ọ̀la ni Olúwa yóò ṣe èyí ni ilẹ̀ yìí.”
6 Olúwa sí ṣe é ni ọjọ́ kejì. Gbogbo ẹran-ọ̀sìn ará Éjíbítì kú, ṣùgbọ́n ẹyọkan kò kú lára ẹran-ọ̀sìn àwọn Ísírẹ́lì.
7 Fáráò rán àwọn ènìyàn rẹ̀ láti lọ ṣe ìwádìí, wọ́n sì rí pé ẹyọkan kò kú lára àwọn ẹran ọ̀sìn ará Ísírẹ́lì. Ṣíbẹ̀ náà, Fáráò kò yí ọkàn rẹ̀ padà àti pé kò jẹ́ kí àwọn ènìyàn ó lọ.