32 Onírúurú ọkà-wíìtì (jéró àti sípélítì) kò bàjẹ́, èṣo wọn padà gbó nítorí wọ́n máa ń pẹ so.)
33 Nígbà náà ni Mósè kúrò ni iwájú Fáráò, ó kúrò ni àárin ìgboro kọjá lọ sí ẹ̀yìn odi ìlú, ó sì gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè sí Olúwa, sísán àrá àti òjò yìnyín ti ń rọ̀ sì dáwọ́ dúró, òjò kò sì rọ̀ sí orí ilẹ̀ mọ́.
34 Nígbà tí Fáráò rí i pé òjò àti yìnyín àti àrá ti ń sán ti dáwọ́ dúró, ó tún ṣè ní ẹ̀ẹ̀kan sí i. Ọkan Fáráò àti àwọn ìjòyè rẹ̀ yigbì.
35 Ọkàn Fáráò sì yigbì, kò sì jẹ́ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ó lọ, bí Olúwa ti sọ láti ẹnu Mósè.