1 Nígbà tí àwọn ọ̀ta Júdà àti Bẹ́ńjámínì gbọ́ wí pé àwọn ìgbèkùn tí ó padà dé ń kọ́ tẹ́ḿpìlì fún Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì,
2 wọ́n wá sí ọ̀dọ̀ Ṣérúbábélì àti sí ọ̀dọ̀ àwọn olórí àwọn ìdílé, wọ́n sì wí pé, “Jẹ́ kí a bá a yín kọ́ nítorí pé, bí i ti yín, a ń wá Ọlọ́run yín, a sì ti ń rúbọ sí i láti ìgbà Ésáríhádónì ọba Ásíríà, tí ó mú wa wá síbi yìí.”
3 Ṣùgbọ́n Ṣerubábélì, Jéṣúà àti ìyókù àwọn olórí àwọn ìdílé Ísírẹ́lì dáhùn pé, “Ẹ kò ní ipa pẹ̀lú wa ní kíkọ́ ilé fún Ọlọ́run wa. Àwa nìkan yóò kọ́ ọ fún Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, bí Sáírúsì, ọba Páṣíà, ti pàṣẹ fún wa.”
4 Nígbà náà ni àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà mú ọwọ́ àwọn ènìyàn Júdà rọ, wọ́n sì dẹ́rù bá wọ́n ní ti kíkọ́ ilé náà.