1 Nígbà tí àwọn ọ̀ta Júdà àti Bẹ́ńjámínì gbọ́ wí pé àwọn ìgbèkùn tí ó padà dé ń kọ́ tẹ́ḿpìlì fún Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì,
2 wọ́n wá sí ọ̀dọ̀ Ṣérúbábélì àti sí ọ̀dọ̀ àwọn olórí àwọn ìdílé, wọ́n sì wí pé, “Jẹ́ kí a bá a yín kọ́ nítorí pé, bí i ti yín, a ń wá Ọlọ́run yín, a sì ti ń rúbọ sí i láti ìgbà Ésáríhádónì ọba Ásíríà, tí ó mú wa wá síbi yìí.”
3 Ṣùgbọ́n Ṣerubábélì, Jéṣúà àti ìyókù àwọn olórí àwọn ìdílé Ísírẹ́lì dáhùn pé, “Ẹ kò ní ipa pẹ̀lú wa ní kíkọ́ ilé fún Ọlọ́run wa. Àwa nìkan yóò kọ́ ọ fún Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, bí Sáírúsì, ọba Páṣíà, ti pàṣẹ fún wa.”
4 Nígbà náà ni àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà mú ọwọ́ àwọn ènìyàn Júdà rọ, wọ́n sì dẹ́rù bá wọ́n ní ti kíkọ́ ilé náà.
5 Wọ́n gba àwọn olùdámọ̀ràn láti ṣiṣẹ́ lòdì sí wọn àti láti sọ ète wọn di asán ní gbogbo àsìkò ìjọba Sáírúsì ọba Páṣíà àti títí dé ìgbà ìjọba Dáríúsì ọba Páṣíà.
6 Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìjọba Ṣérísésì wọ̀n fi ẹ̀sùn kan àwọn ènìyàn Júdà àti Jérúsálẹ́mù.