5 Wọ́n gba àwọn olùdámọ̀ràn láti ṣiṣẹ́ lòdì sí wọn àti láti sọ ète wọn di asán ní gbogbo àsìkò ìjọba Sáírúsì ọba Páṣíà àti títí dé ìgbà ìjọba Dáríúsì ọba Páṣíà.
6 Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìjọba Ṣérísésì wọ̀n fi ẹ̀sùn kan àwọn ènìyàn Júdà àti Jérúsálẹ́mù.
7 Àti ní àkókò ìjọba Aritaṣéṣéṣì ọba Páṣíà, Bíṣílámì, Mítírédátì, Tábélì àti àwọn ẹlẹ́gbẹ̀ rẹ̀ yóòkù kọ̀wé sí Aritaṣéṣéṣì. A kọ ìwé náà ní ìlànà ìkọ̀wé Árámáíkì èdè Árámáíkì sì ní a fi kọ ọ́.
8 Réhúmì balógun àti Ṣímíṣáì akọ̀wé jùmọ̀ kọ́ ìwé láti dojúkọ Jérúsálẹ́mù sí Aritaṣéṣéṣì ọba báyìí:
9 Réhúmì balógun àti Ṣímíṣáì akọ̀wé, pẹ̀lú àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn tó kù—àwọn adájọ́ àti àwọn ìjòyè lórí àwọn ènìyàn láti Tírípólísì, Pásíà, Érékì àti Bábílónì, àwọn ará Élámì ti Súsà,
10 pẹ̀lú àwọn ènìyàn mìíràn tí ẹni ọlá àti ẹni ọ̀wọ̀ Áṣúríbánípálì lé jáde tí ó sì tẹ̀ wọ́n dó sí ìlú Samáríà àti níbòmíràn ní agbègbè e Yúfúrátè.
11 (Èyí ni ẹ̀dà ìwé tí wọ́n fi ránṣẹ́ sí i.)Sí ọba Aritaṣéṣéṣì,Lati ọ̀dọ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àwọn ọkùnrin agbègbè Yúfúrátè: