Ẹ́sírà 6:7-13 BMY

7 Ẹ fi iṣẹ́ ilé Ọlọ́run yìí lọ́rùn sílẹ̀ láì díi lọ́wọ́. Ẹ jẹ́ kí Baálẹ̀ àwọn Júù àti àwọn àgbààgbà Júù tún ilé Ọlọ́run yín kọ́ sí ipò rẹ̀.

8 Síwájú sí i, mo pàṣẹ ohun tí ẹ gbọdọ̀ ṣe fún àwọn àgbààgbà Júù wọ̀nyí lórí kíkọ́ ilé Ọlọ́run yìí:Gbogbo ìnáwó àwọn ọkùnrin yìí ni kí ẹ san lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ lára ìṣúra ti ọba, láti ibi àkójọpọ̀ owó ìlú ti agbègbè Yúfúrátè kí iṣẹ́ náà má bà dúró.

9 Ohunkóhun tí wọ́n bá fẹ́—àwọn akọ ọ̀dọ́ màlúù, àwọn àgbò, ọ̀dọ́ àgùntàn fún ọrẹ sísun sí Ọlọ́run ọ̀run, àti jéró, iyọ̀, wáìnì àti òróró, ìfiyàn bí àwọn àlùfáà ní Jérúsálẹ́mù ti béèrè ni ẹ gbọdọ̀ fún wọn lójoojúmọ́ láì yẹ̀.

10 Kí wọn lè rú àwọn ẹbọ tí ó tẹ́ Ọlọ́run ọ̀run lọ́rùn kí wọ́n sì gbàdúrà fún àlàáfíà ọba àti àwọn ọmọ rẹ̀:

11 Síwájú sí i, mo pàṣẹ pé tí ẹnikẹ́ni bá yí àṣẹ yìí padà, kí fa igi àjà ilé rẹ̀ yọ jáde, kí a sì gbe dúró, kí a si fi òun náà kọ́ sí orí rẹ̀ kí ó wo ilé rẹ̀ palẹ̀ a ó sì sọ ọ́ di ààtàn.

12 Kí Ọlọ́run, tí ó ti jẹ́ kí orúkọ rẹ̀ máa gbé ibẹ̀, kí ó pa gbogbo ọba àti orílẹ̀ èdè rún tí ó bá gbé ọwọ́ sókè láti yí àṣẹ yìí padà tàbí láti wó tẹ́ḿpìlì yìí tí ó wà ní Jérúsálẹ́mù ṣubú.Èmi Dáríúsì n pàṣẹ rẹ̀, jẹ́ kí ó di mímú ṣẹ láì yí ohunkóhun padà.

13 Nígbà náà, nítorí àṣẹ tí ọba Dáríúsì pa, Táténáì, Baálẹ̀ ti agbégbé Yúfúrátè, àti Ṣétarì-Bóṣénáì pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́gbẹ́ wọn pa á mọ́ láì yí ọ̀kan padà.