1 Èyí ni ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ìgbà Sérísésì, tí ó jọba lórí ẹ̀tàdínláàdóje ìletò bẹ̀rẹ̀ láti Índíà títí ó fi dé Etiópíà. (Kúsì)
2 Ní àkókò ìgbà náà ọba Ṣérísésì ń ṣe ìjọba ní orí ìtẹ́ ẹ rẹ̀ ní ilé ìṣọ́ ti Ṣúsà,
3 Ní ọdún kẹta ìjọba rẹ̀, ó se àsè fún gbogbo àwọn ọlọ́lá àti ìjòyè. Àwọn olórí olóógun láti Páṣíà àti Médíà, àwọn ọmọ aládé, àti àwọn ọlọ́lá ìletò wà níbẹ̀ pẹ̀lú.
4 Ó ṣe àfihàn púpọ̀ ọrọ̀ ìjọba rẹ̀ àti dídán àti ògo ọlá ńlá a rẹ̀ fún ọgọ́sàn-án ọjọ́ gbáko.
5 Nígbà tí ọjọ́ wọ̀nyí kọjá, ọba se àsè fún ọjọ́ méje, nínú ọgbà tí ó wà nínú àgbàlá ààfin ọba, gbogbo ènìyàn láti orí ẹni tí ó kéré dé orí ẹni tí ó lọ́lá jùlọ, tí wọ́n wà ní ilé ìṣọ́ ti Súsà.
6 Ọgbà náà ní aṣọ fèrèsé funfun àti aláwọ̀ òféfèé. Àwọn okùn tí a fi aṣọ aláwọ̀ funfun àti aláwọ̀ elésé àlùkò rán ni a fi ta á mọ́ òrùka fàdákà lára àwọn òpó mábù. Àwọn ibùṣùn tí a fi wúrà àti fàdákà ṣe wà níbi pèpéle òkúta tí a fi ń tẹ́lẹ̀ ilé tí ó jẹ́ mábù, píálì àti òkúta olówó iyebíye mìíràn.