4 Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́bìnrin àti àwọn ìwẹ̀fà Ẹ́sítà wá, wọ́n sọ nípa Módékáì fún-un, ó sì wà nínú ìbànújẹ́ ńlá. Ó fi aṣọ ránṣẹ́ síi kí ó wọ̀ ọ́ dípò aṣọ ọ̀fọ̀ tí ó wọ̀, ṣùgbọ́n òun kò gbà wọ́n.
5 Nígbà náà ni Ẹ́sítà pe Hátakì, ọ̀kan nínú àwọn ìwẹ̀fà ọba tí a yàn láti máa jíṣẹ́ fún-un, ó pàṣẹ fún un pé kí ó béèrè ohun tí ó ń dààmú Módékáì àti ohun tí ó ṣe é.
6 Bẹ́ẹ̀ ni Hátakì jáde lọ bá Módékáì ní ìta gbangba ìlú niwájú ẹnu ọ̀nà ọba.
7 Módékáì sọ ohun gbogbo tí ó ṣẹlẹ̀ fún-un, papọ̀ pẹ̀lú iye owó tí Hámánì ti ṣe ipinnu láti san sínú àpò ìṣúra ọba fún ìparun àwọn Júù.
8 Ó sì tún fún un ní ọ̀kan lára ìwé tí ó gbé jáde fún ìparun àwọn, èyí tí a tẹ̀ jáde ní Ṣúṣà, láti fi han Ésítà kí ó sì ṣe àlàyé e rẹ̀ fún-un, ó sì sọ fún-un pé kí ó bẹ̀ ẹ́ kí ó lọ ṣíwájú ọba láti bẹ̀bẹ̀ fún àánú, kí ó bẹ̀bẹ̀ nítorí àwọn ènìyàn an rẹ̀.
9 Hátakì padà ó sì lọ ṣàlàyé fún Ẹ́sítà ohun tí Módékáì sọ.
10 Nígbà náà ni Ésítà pàṣẹ fún un pé kí ó sọ fún Módékáì,