6 Bẹ́ẹ̀ ni Hátakì jáde lọ bá Módékáì ní ìta gbangba ìlú niwájú ẹnu ọ̀nà ọba.
7 Módékáì sọ ohun gbogbo tí ó ṣẹlẹ̀ fún-un, papọ̀ pẹ̀lú iye owó tí Hámánì ti ṣe ipinnu láti san sínú àpò ìṣúra ọba fún ìparun àwọn Júù.
8 Ó sì tún fún un ní ọ̀kan lára ìwé tí ó gbé jáde fún ìparun àwọn, èyí tí a tẹ̀ jáde ní Ṣúṣà, láti fi han Ésítà kí ó sì ṣe àlàyé e rẹ̀ fún-un, ó sì sọ fún-un pé kí ó bẹ̀ ẹ́ kí ó lọ ṣíwájú ọba láti bẹ̀bẹ̀ fún àánú, kí ó bẹ̀bẹ̀ nítorí àwọn ènìyàn an rẹ̀.
9 Hátakì padà ó sì lọ ṣàlàyé fún Ẹ́sítà ohun tí Módékáì sọ.
10 Nígbà náà ni Ésítà pàṣẹ fún un pé kí ó sọ fún Módékáì,
11 “Gbogbo àwọn ìjòyè ọba àti àwọn ènìyàn agbègbè ìjọba rẹ̀ mọ̀ wí pé: fún ẹnikẹ́ni ọkùnrin tàbí obìnrin kan tàbí tí ó bá bá ọba sọ̀rọ̀ láì jẹ́ pé a ránsẹ́ pèé (ọba ti gbé òfin kan kalẹ̀ pé) kíkú ni yóò kú. Ohun kan tí ó le yẹ èyí ni pé, kí ọba na ọ̀pá a góòlùu rẹ̀ síi kí ó sì dá ẹ̀mí rẹ sí. Ṣùgbọ́n, ọgbọ̀n ọjọ́ ti kọjá tí a ti pè mí láti lọ sí ọ̀dọ̀ ọba.”
12 Nígbà tí a sọ ọ̀rọ̀ Ẹ́sítà fún Módékáì,