2 Wọ́n rí àkọsílẹ̀ níbẹ̀ pé Módékáì tí sọ àṣírí Bígítanà àti Térésì, àwọn ìjòyè ọba méjì tí wọ́n ń ṣọ́ ẹnu ọ̀nà, tí wọ́n ń gbérò láti pa ọba Ṣérísésì.
3 Ọba béèrè pé, “Kí ni ọlá àti iyì tí Módékáì ti gbà fún èyí?”Àwọn ìránṣẹ́ẹ rẹ̀ sì dáhùn pé, “Kò tíì sí ohun tí a ṣe fún-un.”
4 Ọba wí pé, “Taa ni ó wà nínú àgbàlá?” Nísinsin yìí Hámánì ṣẹ̀ṣẹ̀ wọ àgbàlá ìta ààfin ni láti sọ fún ọba nípa ṣíṣo Módékáì lórí igi tí ó ti rì fún-un.
5 Àwọn ìránṣẹ́ẹ rẹ̀ sì dáhùn pé, “Hámánì ni ó wà níbẹ̀ ó dúró sí inú àgbàlá.”Ọba pàṣẹ pé, “Ẹ mú un wọlé wá.”
6 Nígbà tí Hámánì wọlé, ọba béèrè lọ́wọ́ọ rẹ̀ pé, “Kí ni kí a ṣe fún ọkùnrin tí inú ọba dùn sí láti bu ọlá fún?”Nísinsìnyìí Hámánì sì ro èyí fúnra rẹ̀ pé, “Taa ni ó wà níbẹ̀ tí ọba fẹ́ dá lọ́lá ju èmi lọ?”
7 Nítorí náà ó dá ọba lóhùn pé, “Fún ọkùnrin tí inú ọba dùn sí láti dá lọ́lá,
8 jẹ́ kí wọn kí ó mú aṣọ ọba èyí tí ọba ń wọ̀ àti ẹṣin tí ọba má a ń gùn, pẹ̀lú ọ̀kan lára adé ọba kí a fi dé e ní orí.