Ẹ́sítà 9:18-24 BMY

18 Àwọn Júù tí ó wà ní Ṣúṣà, kó ara wọn jọ ní ọjọ́ kẹtàlá àti ọjọ́ kẹrìnlá, nígbà tí ó sì di ọjọ́ Kẹẹ̀dógún wọ́n sinmi wọ́n sì ṣe ọjọ́ náà ní ọjọ́ àṣè àti ayọ̀.

19 Nítorí náà ni àwọn Júù-tí wọ́n ń gbé ní ìletò ṣe pa ọjọ́ kẹrìnlá oṣù Ádárì mọ́ gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ ayọ̀ àti ọjọ́ àṣè, ọjọ́ tí wọ́n ń fún ara wọn ní ẹ̀bùn.

20 Módékáì ṣe àkọsílẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí, ó sì kọ ìwé ránṣẹ́ sí gbogbo àwọn Júù jákèjádò àgbáyé ọba Ṣéríṣésì, tí ó wà ní tòòsí àti àwọn tí ó wà ní jìnnà réré,

21 Láti lè máa ṣe àjọyọ̀ ní ọjọ́ kẹrìnlá àti ọjọ́ kẹẹ̀dógún oṣù Ádárì ní ọdọọdún

22 Gẹ́gẹ́ bí àkókò tí àwọn Júù gba ìsinmi kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀ta a wọn, àti bí oṣù tí ìbànújẹ́ ẹ wọn yí padà di ayọ̀ àti tí ọjọ́ ọ̀fọ̀ wọn di ọjọ́ àjọyọ̀. Ó kọ ọ́ sí wọn láti máa pa ọjọ́ náà mọ́ gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ àṣè àti ọjọ́ ayọ̀ kí wọn sì máa fi oúnjẹ fún ara wọn, kí wọn sì máa fi ẹ̀bùn fún àwọn aláìní.

23 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn Júù gbà láti máa ṣe àjọyọ̀ tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀, wọ́n ń ṣe bí Módékáì ti kọ̀wé sí wọn.

24 Nítorí Hámánì ọmọ Hámédátà, aráa Ágágì, ọ̀ta gbogbo àwọn Júù, ti gbérò sí àwọn Júù láti pa wọ́n run, ó sì ti di Púrì (èyí tí í ṣe ìbò) fún ìṣọdahoro àti ìparun wọn.