1 “Nígbà tí Ísírẹ́lì wà ní ọmọdé mo fẹ́ràn rẹ̀,mo sì pe ọmọ mi jáde wá láti Éjíbítì.
2 Wọ́n rúbọ sí Báálì bí mo ṣe ń pe Ísírẹ́lì síbẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ń sá kúrò lọ́dọ̀mi jìnnà sí i: wọn rúbọ sí báálímu,wọn sì fi tùràrí jóná sí ère fínfín.
3 Lóòtọ́ mo kọ́ Éfúráímù pẹ̀lú ní ìrìnmo di wọ́n mú ní apá,ṣùgbọ́n wọn kò mọ̀pé mo ti mú wọn lára dá.
4 Mo fó okùn ènìyàn fà wọ́nàti ìdè ìfẹ́.Mo mú àjàgà kúrò ni ọrùn wọnMo sì farabalẹ̀ fún wọn ni oúnjẹ.
5 “Ṣé wọn ò wá ní padà sí Éjíbítì bíṢé Ásíríà kò sì ní jẹ ọba lé wọn lórí bínítorí pé wọ́n kọ̀ jálẹ̀ láti ronú pìwàdà?