1 Olúwa sì wí fún mi pé, “Lọ, fi ìfẹ́ hàn sí ìyàwó rẹ̀ padà bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹlòmíràn ti fẹ́ ẹ, tí òun sì tún jẹ́ alágbèrè. Fẹ́ ẹ gẹ́gẹ́ bí Olúwa ṣe fẹ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti tẹ́lé àwọn òrìṣà tí ó sì fẹ́ràn oúnjẹ tí àwọn aláìkọlà yà sọ́tọ̀.”
2 Nítorí náà, mo sì rà á padà ní ṣékélì fàdákà mẹ́ẹ̀dógún (15) àti Ómírì kan àti lẹ́tíkì báálì kan.
3 Mo sì sọ fún un pé, “Ìwọ gbọdọ̀ máa gbé pẹ̀lú mi fún ọjọ́ pípẹ́, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe àgbèrè mọ́ tàbí kí o fẹ́ ọkùnrin mìíràn, èmi náà yóò sì gbé pẹ̀lú ù rẹ.”
4 Nítorí pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóò wà fún ọjọ́ pípẹ́ láì ní ọba tàbí olórí, láìsí ìrúbọ tàbí pẹpẹ mímọ́ láìsí àlùfáà tàbí òrìṣà kankan.
5 Lẹ́yìn èyí ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóò padà láti wá Olúwa Ọlọ́run wọn àti Dáfídì ọba wọn. Wọn yóò sì wá síwájú Olúwa pẹ̀lú ẹ̀rù, wọn ó sì jọ̀wọ́ ara wọn fún Olúwa àti ìbùkún rẹ̀ ní ọjọ́ ìkẹyìn.