8 “Éfúráímù ti darapọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn náà;Éfúráímù jẹ́ àkàrà tí a kò yípadà
9 Àwọn àlejò ti jẹ agbára rẹ̀ runṣùgbọ́n kò sì mọ̀,Ewú ti wà ní orí rẹ̀ káàkiribẹ́ẹ̀ ni kò kíyèsíi
10 Ìgbéraga Ísírẹ́lì ń jẹ́rìí sí iṣùgbọ́n pẹ̀lú gbogbo èyíkò padà sí ọ̀dọ̀ OlúwaỌlọ́run, tàbí kí ó wá a.
11 “Éfúráímù dàbí àdàbàtó rọrùn láti tàn jẹ àti aláìgbọ́ntó wá ń pé Éjíbítì nísinsìn yìító sì tún ń padà lọ si Ásíríà.
12 Nígbà tí wọ́n bá lọ, èmi ó ta àwọ̀n mi sórí wọnÈmi ó fà wọ́n lulẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹyẹ ojú ọ̀runNígbà tí mo bá gbọ́ pé wọ́n rìn pọ̀Èmi nà wọ́n bí ìjọ ènìyàn wọn ti gbọ́
13 Ègbé ní fún wọn,nítorí pé wọ́n ti yà kúrò lọ́dọ̀ mi!Ìparun wà lórí wọn,nítorí pé wọ́n ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi!Èmi yóò rà wọ́n padà.Ṣùgbọ́n wọ́n ń parọ́ mọ́ mi
14 Wọn kò kégbe pè mí láti ọkàn wọn,Ṣùgbọ́n wọ́n ń pohùn réré ẹkún lórí ibùsùn wọn.Wọ́n kó ara wọn jọ, nítorí ọkà àti wáìnìṣùgbọ́n wọ́n yípadà kúrò ní ọ̀dọ̀ mi.