6 “Jẹ́ alágbára, kí o sì mú àyà le; nítorí ìwọ ni yóò ṣe amọ̀nà àwọn ènìyàn wọ̀nyí; láti lè jogún ilẹ̀ tí mo ti búra fún àwọn baba ńlá a wọn láti fi fún wọn.
7 Jẹ́ alágbára, kí o sì mú àyà le gidigidi. Kí o sì sọ́ra láti pa gbogbo òfin tí Móṣè ìránṣẹ́ mi fún ọ mọ́, Má ṣe yà kúrò nínú u rẹ̀ sí ọ̀tún tàbí sí òsì, kí ìwọ kí ó lè ṣe rere níbikíbi tí ìwọ bá ń lọ.
8 Má ṣe jẹ́ kí Ìwé Ofin yìí kúrò ní ẹnu ù rẹ, máa ṣe àṣàrò nínú u rẹ̀ ní ọ̀ṣán àti ní òru, kí ìwọ kí ó lè ṣọ́ra láti ṣe gbogbo nǹkan tí a kọ sí inú u rẹ̀. Nígbà náà ni yóò dára fún ọ, ìwọ yóò sì ní àṣeyọrí.
9 Èmi kò ha ti pàṣẹ fún ọ bí? Jẹ́ alágbára kí o sì mú àyà le. Má ṣe bẹ̀rù, má sì se rẹ̀wẹ̀sì, nítorí pé Olúwa à rẹ yóò wà pẹ̀lú ù rẹ ní ibikíbi tí ìwọ bá ń lọ.”
10 Báyìí ni Jóṣúà pàṣẹ fún olórí àwọn ènìyàn rẹ̀
11 “Ẹ la ibùdó já, kí ẹ sì sọ fún àwọn ènìyàn, Ẹ pèṣè oúnjẹ yín sílẹ̀. Ní ìwòyí ọ̀túnla, ẹ̀yin yóò la Jọ́dánì yìí kọjá, láti gba ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run yín fi fún un yín láti ní.”
12 Ṣùgbọ́n Jóṣúà sọ fún àwọn ará a Rúbẹ́nì, àwọn ará Gádì àti fún ìdajì ẹ̀yà Mánásè pé,