Jóṣúà 9 BMY

Ìwa Àrékérekè Gíbíónì

1 Nísinsinyìí, nígbà tí gbogbo ọba tó wà ní ìwọ̀-oòrùn Jọ́dánì gbọ́ nípa nǹkan wọ̀nyí, àwọn náà tí ó wà ní orí òkè àti àwọn tí ó wà ní ẹṣẹ̀ òkè, àti gbogbo àwọn tí ó wà ní agbégbé Òkun ńlá títí ó fi dé Lẹ́bánónì (àwọn ọba Hítì Ámórì, Kénánì, Pérísì Hífì àti Jébúsì)

2 wọ́n sì kó ara wọn jọ láti bá Jósúà àti Ísírẹ́lì jagun.

3 Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ènìyàn Gíbíónì gbọ́ ohun tí Jóṣúà ṣe sí Jẹ́ríkò àti Áì,

4 wọ́n dá ọgbọ́n ẹ̀tàn. Wọ́n lọ bí aṣojú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn: tí kún fún àwọn àpò tó ti gbó, àti àwọn awọ ọtí wáìnì tó ti gbó tí a tún rán.

5 Àwọn ọkùnrin náà sì wọ bàtà àti aṣọ tí ó ti gbó. Gbogbo oúnjẹ tí wọ́n pèsè fún ara wọn sì bu.

6 Wọ́n sì tọ Jóṣúà lọ ní ibùdó ní Gílígálì, wọ́n sì sọ fún òun àti àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì pé, “Ìlú òkèrè ní àwọn ti wá, ẹ ṣe àdéhùn àlàáfíà pẹ̀lú wa.”

7 Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì sọ fún àwọn ará Hífì pé, “Ṣùgbọ́n bóyá tòsí wa ni ẹ ń gbé. Báwo ni a ó ṣe lè se àdéhùn pẹ̀lú yín?”

8 “Ìránṣẹ́ rẹ ní àwa í ṣe.” Wọ́n sọ fún Jóṣúà.Ṣùgbọ́n Jóṣúà béèrè, “Ta ni yín àti pé níbo ni ẹ̀yín ti wá?”

9 Wọ́n sì dáhùn pé: “Ní ilẹ̀ òkèèrè ní àwọn ìránṣẹ́ rẹ tí wá, nítorí orúkọ Olúwa Ọlọ́run rẹ. Nítorí tí àwa ti gbọ́ òkìkí rẹ àti ohun gbogbo tí ó ti ṣe ní Éjíbítì,

10 àti ohun gbogbo tí ó ti ṣe sí ọba àwọn Ámórì méjèèje tí ń bẹ ní òkè Jọ́dánì, sí Síhónì ọba Héṣíbónì, àti Ógù ọba Básánì, tí wọ́n jọba ní Áṣítarótù.

11 Àwọn àgbà wa àti gbogbo àwọn tí ń gbé ìlú wa sọ fún wa pé, ‘Ẹ mú oúnjẹ lọ́wọ́ fún ìrìnàjò yín, ẹ lọ pàdé wọn, kí ẹ sì sọ fún wọn pé, “Àwa ni ìránṣẹ́ yín, ẹ dá àdéhùn pẹ̀lú wa.” ’

12 Gbígbóná ní a mú oúnjẹ ní ojí nílé ní oji tí à ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ yín. Ṣùgbọ́n ẹ wò ó bí ó ṣe gbẹ àti bí ó sì ṣe bu nísinsinyí.

13 Àti ìgò wáìnì wọ̀nyí, tí àwa rọ kún tuntun ni, ṣùgbọ́n ẹ wò ó bí wọ́n ti sán. Asọ àti bàtà wa ni ó sì ti gbó nítorí ìrìnàjò ọ̀nà jínjìn.”

14 Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì sì yẹ oúnjẹ wọn wò, wọn kò sì wádìí ní ọwọ́ Olúwa.

15 Nígbà náà ni Jósúà ṣe àdéhùn àlàáfíà pẹ̀lú wọn láti dá wọn sí, àti àwọn olórí ìjọ ènìyàn fi ọwọ́ sí àdéhùn náà nípa ṣíṣe ìbúra.

16 Ní ẹ̀yìn ọjọ́ mẹ́ta tí wọ́n ti ṣe àdéhùn pẹ̀lú àwọn ará Gíbíónì, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbọ́ pé aládùúgbò wọn ni wọ́n, tí ń gbé ní tòsí wọn.

17 Bẹ́ẹ̀ ní àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde, wọ́n sì dé ìlú wọn ní ọjọ́ kẹ́ta: Gíbíónì, Kéfírà, Béérótù àti Kiriati-jéárímù.

18 Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò si kọlù wọ́n, nítorí pé àwọn àgbààgbà ìjọ ènìyàn ti búra fún wọn ní orúkọ Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì.Gbogbo ènìyàn sì kùn sí àwọn àgbààgbà náà,

19 ṣùgbọ́n gbogbo àwọn olórí dáhùn pé, “Àwa ti búra fún wọn ní orúkọ Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì, a kò sì lè fọwọ́ kàn wọ́n nísinsinyí.

20 Èyí ní àwa yóò ṣe sí wọn, Àwa yóò dá wọn sí, kí ìbínú kí ó má baà wá sorí wa, nítorí ìbúra tí a búra fún wọn.”

21 Wọ́n tẹ̀ṣíwájú, “Ẹ dá wọn sí, ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí wọn jẹ́ gégigégi àti apọnmi fún gbogbo ìlú.” Àwọn àgbààgbà náà sì mú ìlérí wọn sẹ fún wọn.

22 Nígbà náà ni Jósúà pe àwọn ọmọ Gíbíónì jọ pé, “Èé ṣe tí ẹ̀yin fí tàn wá wí pe, ‘Àwa gbé ní ibi tí ó jìnnà sí yín,’ nígbà tí ó jẹ́ pé tòsí wa ní ẹ̀yin ń gbé?

23 Nísinsinyí, ẹ̀yin di ẹni ègún: Ẹ̀yin kò sì ní kúrò ní gégigégi àti apọnmi fún ilé Ọlọ́run mi.”

24 Wọ́n sì dá Jóṣúà lóhùn pé, “Nítorí tí a sọ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ dájú ṣáká bí Olúwa Ọlọ́run rẹ ti pàṣẹ fún Mósè ìránṣẹ́ rẹ̀, láti fún yín ní gbogbo ilẹ̀ náà, kí ó sì pa gbogbo olùgbé ilẹ̀ náà run kúrò ní iwájú yín. Nítorí náà, àwa bẹ̀rù ẹ̀mí wa nítorí yín, èyí sì ni ìdí tí a fi ṣe bẹ́ẹ̀.

25 Nísinsinyí, àwa wà ní ọwọ́ yín. Ohunkóhun tí ẹ bá rò pé ó yẹ ó si tọ́ lójú yín ní kí ẹ fi wá ṣe.”

26 Bẹ́ẹ̀ ní Jóṣúà sì gbà wọ́n là kúrò ní ọwọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Wọn kò sì pa wọ́n.

27 Ní ọjọ́ náà ni ó sọ àwọn Gíbíónì di aṣẹ́gi àti apọnmi fún àwọn ará ìlú àti fún pẹpẹ Olúwa ní ibi tí Olúwa yóò yàn. Báyìí ní wọ́n wà títí di òní yìí.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24