Jóṣúà 20 BMY

Àwọn Ìlú Ààbò.

1 Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Jósúà pé,

2 “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọn yan àwọn ìlú ààbò, gẹ́gẹ́ bí mo ti pàṣẹ fún ọ láti ẹnu Mósè,

3 kí ẹni tí ó bá sèèsì pa ènìyàn tàbí tí ó bá pa ènìyàn láìmọ̀ọ́mọ̀ lè sálọ sí ibẹ̀, fún ààbò lọ́wọ́ olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ ẹni tí ó pa.

4 “Nígbà tí ó bá sálọ sí ọ̀kan nínú àwọn ìlú wọ̀nyí, yóò sì dúró ní ẹnu ọ̀nà àtiwọ ibodè ìlú, kí ó sì ṣe àlàyé ara rẹ̀ ní iwájú àwọn àgbààgbà ìlú náà. Nígbà náà ni wọn yóò gbà á sí ìlú wọn, wọn yóò sì fun ní ibùgbé láàárin wọn.

5 Bí olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ bá ń lépa wọn, wọn kò gbọdọ̀ fi àwọn ọ̀daràn náà lé wọn lọ́wọ́, nítorí.

6 Òun ó sì máa gbé inú ìlú náà, títí yóò fi jẹ́jọ́ níwájú ìjọ ènìyàn àti títí ikú olórí àlùfáà tí ó ń siṣẹ́ ìsìn nígbà náà. Nígbà náà ó lè padà sí ilé rẹ̀ ní ìlú tí ó ti sá wá.”

7 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n yan Kedésì ní Gálílì ní ìlú òkè Náfítanì, Sékémù ní ìlú òkè Éfúráímù, àti Kíríátì aginjù (tí í ṣe, Hébúrónì) ní ìlú òkè Júdà.

8 Ní ìhà ìlà oòrùn Jọ́dánì ti Jẹ́ríkò, wọ́n ya Bésẹ́rìù ní aṣalẹ̀ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ ní ẹ̀yà Rúbẹ́nì, Rámótì ní Gílíádì ní ẹ̀yà Gádì, àti Golanì ní Básánì ní ẹ̀yà Mánásè.

9 Ẹnikẹ́ni nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tàbí àlejò tí ń gbé ní àárin wọn tí ó sèèsì pa ẹnìkan lè sálọ sí àwọn ìlú tí a yà sọ́tọ̀ wọ̀nyí, kí olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ má sì ṣe pa á kí ó to di àkókò tí yóò jẹ́jọ́ níwájú ìjọ ènìyàn.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24