Jóṣúà 12 BMY

Orúkọ Àwọn Ọba Tí A Ṣẹ́gun.

1 Ìwọ̀nyí ní àwọn ọba ilẹ̀ náà tí àwọn ará Ísírẹ́lì ṣẹ́gun, tí wọ́n sì gba ilẹ̀ wọn ní ìlà-oòrùn Jọ́dánì, láti Ánónì-Gọ́gi dé Okè Hámónì, pẹ̀lú gbogbo ìhà ìlà-oòrùn aginjù:

2 Síhónì ọba àwọn Ámorì,tí ó jọba ní Hésíbónì. Ó ṣe àkóso láti Ároérì tí ń bẹ ní etí Anoni-Gọ́gì, láti àárin Jọ́ọ́jì dé Odò Jábókì, èyí tí ó jẹ́ ààlà àwọn ọmọ Ámónì. Pẹ̀lú ìdajì àwọn ará Gílíádì.

3 Ó sì se àkóso ní orí ìlà-oòrùn aginjù láti Òkun Kínẹ́rétì sí ìhà Òkun ti aginjù (Òkun Iyọ̀), sí Bẹti-Jésímótù, àti láti gúsù lọ dé ìsàlẹ̀ ẹsẹ̀ òkè Písígà.

4 Àti agbégbé Ógù ọba Básánì,ọ̀kan nínú àwọn tí ó kù nínú àwọn ará Ráfíátì, ẹni tí ó jọba ní Ásítarótù àti Édírì.

5 Ó se àkóso ní orí Okè Hámónì, Sálékà, Básánì títí dé ààlà àwọn ènìyàn Gésúrì àti Máákà, àti ìdajì Gílíádì dé ààlà Síhónì ọba Hésíbónì.

6 Mósè ìránṣẹ́ Olúwa àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì borí wọn. Mósè ìránṣẹ́ Olúwa sì fi ilẹ̀ wọn fún àwọn ẹ̀yà Rúbẹ́nì, àwọn ẹ̀yà Gádì àti ìdajì ẹ̀yà Mánásè kí ó jẹ́ ohun ìní wọn.

7 Ìwọ̀nyí ní àwọn ọba ilẹ̀ náà tí Jóṣúà àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sẹ́gun ní ìhà ìwọ̀-oòrùn Jọ́dánì, láti Báálì Gádì ní Àfonífojì Lẹ́bánónì sí Okè Hálákì, èyí tí O lọ sí ọ̀nà Sérì (Jóṣúà sì fi ilẹ̀ wọn fún àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì ní ilẹ̀ ìní gẹ́gẹ́ bí ìpín ẹ̀yà wọn:

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24