Jóṣúà 4 BMY

1 Nígbà tí gbogbo orílẹ̀-èdè náà kọjá nínú odò Jọ́dánì tan, Olúwa ṣọ fún Jóṣúà pé,

2 “Yan ọkùnrin méjìlá (12) nínú àwọn ènìyàn, ẹnìkan nínú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan,

3 kí o sì pàṣẹ fún wọn pé Ẹ gbé òkúta méjìlá (12) láti àárin odò Jọ́dánì ní ibi tí àwọn àlùfáà dúró sí, kí ẹ sì rù wọn kọjá, kí ẹ sì gbé wọn sí ibi tí ẹ̀yin yóò sùn ní alẹ́ yìí.”

4 Bẹ́ẹ̀ ni Jóṣúà pe àwọn ọkùnrin méjìlá (12) tí ó ti yàn nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ẹnìkan nínú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kàn,

5 ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ kọjá lọ ní iwájú àpótí ẹ̀rí Olúwa Ọlọ́run yín sí àárin odò Jọ́dánì. Kí olúkúlùkù yín gbé òkúta kọ̀ọ̀kan lé èjìká a rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí iye ẹ̀yà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì,

6 kí ó sì jẹ́ àmì láàrin yín. Ní ọjọ́ iwájú, nígbà tí àwọn ọmọ yín bá béèrè lọ́wọ́ ọ yín pé, ‘Kí ni òkúta wọ̀nyí dúró fún?’

7 Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò dá wọn lóhùn pé, nítorí a gé omi odò Jọ́dánì kúrò ní iwájú àpótí ẹ̀rí Olúwa. Nígbà tí a rékọjá a Jọ́dánì, a gé omi Jọ́dáni kúrò. Àwọn òkúta wọ̀nyí yóò sì jẹ́ ìrántí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láéláé.”

8 Báyìí ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ṣe bí Jóṣúà ti paláṣẹ fún wọn. Wọ́n gbé òkúta méjìlá láti àárin odò Jọ́dánì gẹ́gẹ́ bí iye ẹ̀yà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, bí Olúwa ti sọ fún Jóṣúà; wọ́n sì rù wọ́n kọjá lọ sí ibùdó, ní ibi tí wọ́n ti gbé wọn kalẹ̀.

9 Jóṣúà sì to òkúta méjìlá (12) náà sí àárin odò Jọ́dánì fún ìrántí ní ọ̀kánkán ibi tí àwọn àlùfáà tí ó ru àpótí ẹ̀rí dúró sí. Wọ́n sì wà níbẹ̀ di òní yìí.

10 Àwọn àlùfáà tí ó ru àpótí náà dúró ní àárin Jọ́dánì títí gbogbo nǹkan tí Olúwa pa láṣẹ Jóṣúà di síṣe ní paṣẹ̀ àwọn ènìyàn, gẹ́gẹ́ bí Móṣè ti pàṣẹ fún Jóṣúà. Àwọn ènìyàn náà sì yára kọjá,

11 bí gbogbo wọn sì ti rékọjá tán, ni àpótí ẹ̀rí Olúwa àti àwọn àlùfáà wá sí òdì kejì. Bí àwọn ènìyàn sì ti ń wò wọ́n.

12 Àwọn ọkùnrin Rúbẹ́nì, Gádì àti ìdajì ẹ̀yà Mànásè náà sì rékọjá ní ìhámọ́ra ogun níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, gẹ́gẹ́ bí Móṣè ti pàṣẹ fún wọn.

13 Àwọn bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogójì (40,000) tó ti múra fún ogun rékọjá lọ ní iwájú Olúwa sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jẹ́ríkò láti jagun.

14 Ní ọjọ́ náà ni Olúwa gbé Jóṣúà ga ní ojú gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, wọ́n sì bẹ̀rù u rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé e wọn, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti bẹ̀rù Móṣè.

15 Olúwa sì sọ fún Jóṣúà pé,

16 “Pàṣẹ fún àwọn àlùfáà tí o ń ru àpótí ẹ̀rí, kí wọn kí ó jáde kúrò nínú odò Jọ́dánì.”

17 Bẹ́ẹ̀ ni Jóṣúà pàṣẹ fún àwọn àlùfáà pé, “Ẹ jáde kúrò nínú odò Jọ́dánì.”

18 Àwọn àlùfáà náà jáde láti inú odò pẹ̀lú apòtí ẹ̀rí ni orí wọn. Bí wọ́n ti fi ẹṣẹ̀ ẹ wọn tẹ orí ilẹ̀ gbígbẹ ni omi Jọ́dánì náà padà sí àyè e rẹ̀, o sì kún wọ bèbè bí i ti àtẹ̀yìn wá.

19 Ní ọjọ́ kẹwàá (10) osù kìn-ní-ní (1) àwọn ènìyàn náà lọ láti Jọ́dánì, wọ́n sì dúró ní Gílígálì ní ìlà-oòrùn Jẹ́ríkò.

20 Jóṣúà sì to àwọn òkúta méjìlá (12) tí wọ́n mú jáde ní Jọ́dánì jọ ní Gílígálì.

21 Ó sì sọ fún àwọn ará Ísírẹ́lì, “Ní ọjọ́ iwájú nígbà tí àwọn ọmọ yín bá béèrè ní ọwọ́ baba wọn pé, ‘Kí ni òkúta wọ̀nyí yìí dúró fún?’

22 Nígbà náà ni ẹ ó jẹ́ kí àwọn ọmọ yín mọ̀ pé, ‘Ísírẹ́lì rékọjá odò Jọ́dánì ní orí ilẹ̀ gbígbẹ.’

23 Nítorí Olúwa Ọlọ́run yín mú Jọ́dánì gbẹ ní iwájú u yín títí ẹ̀yin fi kọjá. Olúwa Ọlọ́run yín ti ṣe sí Jọ́dánì gẹ́gẹ́ bí ó ti se sí Òkun Pupa, nígbà tí ó mú un gbẹ ní iwájú wa títí àwa fi kọjá.

24 Ó ṣe èyí kí gbogbo ayé lè mọ̀ pé ọwọ́ Olúwa ní agbára, àti kí ẹ̀yin kí ó lè máa bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run yín ní ìgbà gbogbo.”

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24