Jóṣúà 1:8-14 BMY

8 Má ṣe jẹ́ kí Ìwé Ofin yìí kúrò ní ẹnu ù rẹ, máa ṣe àṣàrò nínú u rẹ̀ ní ọ̀ṣán àti ní òru, kí ìwọ kí ó lè ṣọ́ra láti ṣe gbogbo nǹkan tí a kọ sí inú u rẹ̀. Nígbà náà ni yóò dára fún ọ, ìwọ yóò sì ní àṣeyọrí.

9 Èmi kò ha ti pàṣẹ fún ọ bí? Jẹ́ alágbára kí o sì mú àyà le. Má ṣe bẹ̀rù, má sì se rẹ̀wẹ̀sì, nítorí pé Olúwa à rẹ yóò wà pẹ̀lú ù rẹ ní ibikíbi tí ìwọ bá ń lọ.”

10 Báyìí ni Jóṣúà pàṣẹ fún olórí àwọn ènìyàn rẹ̀

11 “Ẹ la ibùdó já, kí ẹ sì sọ fún àwọn ènìyàn, Ẹ pèṣè oúnjẹ yín sílẹ̀. Ní ìwòyí ọ̀túnla, ẹ̀yin yóò la Jọ́dánì yìí kọjá, láti gba ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run yín fi fún un yín láti ní.”

12 Ṣùgbọ́n Jóṣúà sọ fún àwọn ará a Rúbẹ́nì, àwọn ará Gádì àti fún ìdajì ẹ̀yà Mánásè pé,

13 “Rántí àṣẹ tí Móṣè ìránṣẹ́ Olúwa pa fún yín: ‘Olúwa Ọlọ́run yín á fún yin ní ìsinmi, òun yóò sì fún un yín ní ilẹ̀ yìí.’

14 Àwọn ìyàwó yín, àwọn ọmọ yín àti àwọn ẹran ọ̀sìin yín lè dúró ní ilẹ̀ tí Móṣè fún un yin ní ìlà-oòrùn Jọ́dánì; ṣùgbọ́n gbogbo àwọn jagunjagun un yín, pẹ̀lú ìhámọ́ra ogun gbọdọ̀ kọjá ṣíwájú àwọn arákùnrin yín. Ẹ̀yin yóò sì rán àwọn arákùnrin yín lọ́wọ́