1 Ìwọ̀nyí ní àwọn ọba ilẹ̀ náà tí àwọn ará Ísírẹ́lì ṣẹ́gun, tí wọ́n sì gba ilẹ̀ wọn ní ìlà-oòrùn Jọ́dánì, láti Ánónì-Gọ́gi dé Okè Hámónì, pẹ̀lú gbogbo ìhà ìlà-oòrùn aginjù:
2 Síhónì ọba àwọn Ámorì,tí ó jọba ní Hésíbónì. Ó ṣe àkóso láti Ároérì tí ń bẹ ní etí Anoni-Gọ́gì, láti àárin Jọ́ọ́jì dé Odò Jábókì, èyí tí ó jẹ́ ààlà àwọn ọmọ Ámónì. Pẹ̀lú ìdajì àwọn ará Gílíádì.
3 Ó sì se àkóso ní orí ìlà-oòrùn aginjù láti Òkun Kínẹ́rétì sí ìhà Òkun ti aginjù (Òkun Iyọ̀), sí Bẹti-Jésímótù, àti láti gúsù lọ dé ìsàlẹ̀ ẹsẹ̀ òkè Písígà.
4 Àti agbégbé Ógù ọba Básánì,ọ̀kan nínú àwọn tí ó kù nínú àwọn ará Ráfíátì, ẹni tí ó jọba ní Ásítarótù àti Édírì.