11 Àti Gílíádì, ní agbégbé àwọn ènìyàn Gésúrì àti Máákà, gbogbo Okè Hámónì àti gbogbo Básánì títí dé Sálẹ́kà,
12 Ìyẹn, gbogbo ilẹ̀ ọba Ógù ní Básánì, tí ó jọba ní Áṣítarótù àti Édérì, ẹni tí ó kù nínú àwọn Réfáítì ìyókù. Mósè ti ṣẹ́gun wọn, ó sì ti gba ilẹ̀ wọn.
13 Ṣùgbọ́n àwọn ará Ísírẹ́lì kò lé àwọn ará Géṣúrì àti Máákà jáde, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń gbé ní àárin àwọn ará Ísírẹ́lì títí di òní yìí.
14 Ṣùgbọ́n àwọn ẹ̀yà Léfì ni kò fi ogún kankan fún, níwọ̀n ìgbà tí ó ti jẹ́ pé ọrẹ àfinásun sí Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì ni ogún tiwọn, gẹ́gẹ́ bí o ti ṣèlérí fún wọn.
15 Èyí ni Mósè fi fún ẹ̀yà Rúbẹ́nì ni agbo ilé sí agbo ilé:
16 Láti agbégbé Áréórì ní etí Ánónì Jọ́ọ́jì àti láti ìlú tí ń bẹ láàrin Jọ́ọ́jì, àti gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀ ní ìkọjá Médébà
17 sí Héṣibónì àti gbogbo ìlú rẹ̀ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, pẹ̀lú Débónì, Bámótì, Báálì, Bẹti-Báálì Míónì,