14 Ṣùgbọ́n àwọn ẹ̀yà Léfì ni kò fi ogún kankan fún, níwọ̀n ìgbà tí ó ti jẹ́ pé ọrẹ àfinásun sí Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì ni ogún tiwọn, gẹ́gẹ́ bí o ti ṣèlérí fún wọn.
15 Èyí ni Mósè fi fún ẹ̀yà Rúbẹ́nì ni agbo ilé sí agbo ilé:
16 Láti agbégbé Áréórì ní etí Ánónì Jọ́ọ́jì àti láti ìlú tí ń bẹ láàrin Jọ́ọ́jì, àti gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀ ní ìkọjá Médébà
17 sí Héṣibónì àti gbogbo ìlú rẹ̀ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, pẹ̀lú Débónì, Bámótì, Báálì, Bẹti-Báálì Míónì,
18 Jáhásì, Kédẹ́mótì, Méfáátì,
19 Kíríátaímù, Síbímà, Sẹrétì Sháárì lórí òkè ní àfonífojì.
20 Bẹti-Péórì, gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Písígà, àti Bẹti-Jésímátì