16 Láti agbégbé Áréórì ní etí Ánónì Jọ́ọ́jì àti láti ìlú tí ń bẹ láàrin Jọ́ọ́jì, àti gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀ ní ìkọjá Médébà
17 sí Héṣibónì àti gbogbo ìlú rẹ̀ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, pẹ̀lú Débónì, Bámótì, Báálì, Bẹti-Báálì Míónì,
18 Jáhásì, Kédẹ́mótì, Méfáátì,
19 Kíríátaímù, Síbímà, Sẹrétì Sháárì lórí òkè ní àfonífojì.
20 Bẹti-Péórì, gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Písígà, àti Bẹti-Jésímátì
21 gbogbo ìlú tí ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀e àti gbogbo agbégbé Síhónì ọba Ámórì, tí ó ṣe àkóso Héṣíbónì. Mósè sì ti sẹ́gun rẹ̀ àti àwọn ọmọ ìjòyè Mídíánì, Éfì, Rékémì, Súrì, Húrì àti Rébà, àwọn ọmọ ọba pàmọ̀pọ̀ pẹ̀lú Síhónì tí ó gbé ilẹ̀ náà.
22 Ní àfikún àwọn tí a pa ní ogun, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi idà pa Bálámù ọmọ Béórì alásọtẹ́lẹ̀.