23 Ààlà àwọn ọmọ Rúbẹ́nì ni etí odò Jọ́dánì. Àwọn ìlú wọ̀nyí àti abúlé rẹ̀ ni ilẹ̀ ìní àwọn ọmọ Rúbẹ́nì ní agbo ilé ní agbo ilé.
24 Èyí ni ohun tí Mósè ti fi fún ẹ̀yà Gádì, ní agbo ilé ní agbo ilé:
25 Agbègbè ìlú Jásérì, gbogbo ìlú Gílíádì àti ìdajì orílẹ̀ èdè àwọn ọmọ ará Ámónì títí dé Áróérì ní ẹ̀bá Rábà;
26 àti láti Hésíbónì lọ sí Ramati-Mísífà àti Bétónímù, àti láti Móhánáimù sí agbégbé ìlú Débírì,
27 àti ní àfonífojì Bẹti-Hárámù, Bẹti-Nímírà, Súkótìọ àti Sáfónì pẹ̀lú ìyókù agbégbé ilẹ̀ Síhónì ọba Héṣíbónì (ní ìhà ìlà oòrùn Jọ́dánì, agbégbé rẹ̀ títí dé òpin Òkun Kínẹ́rítì).
28 Àwọn ìlú wọ̀nyí àti abúlé rẹ̀ jẹ́ ogún àwọn ọmọ Gádì, ní agbo ilé ní agbo ilé.
29 Èyí ni ohun tí Mósè ti fi fún ìdajì ẹ̀yà Mánásè, èyí ni pé, fún ìdajì ìdílé irú ọmọ Mánásè, ní agbo ilé ní agbo ilé: