26 àti láti Hésíbónì lọ sí Ramati-Mísífà àti Bétónímù, àti láti Móhánáimù sí agbégbé ìlú Débírì,
27 àti ní àfonífojì Bẹti-Hárámù, Bẹti-Nímírà, Súkótìọ àti Sáfónì pẹ̀lú ìyókù agbégbé ilẹ̀ Síhónì ọba Héṣíbónì (ní ìhà ìlà oòrùn Jọ́dánì, agbégbé rẹ̀ títí dé òpin Òkun Kínẹ́rítì).
28 Àwọn ìlú wọ̀nyí àti abúlé rẹ̀ jẹ́ ogún àwọn ọmọ Gádì, ní agbo ilé ní agbo ilé.
29 Èyí ni ohun tí Mósè ti fi fún ìdajì ẹ̀yà Mánásè, èyí ni pé, fún ìdajì ìdílé irú ọmọ Mánásè, ní agbo ilé ní agbo ilé:
30 Ilẹ̀ náà fẹ̀ dé Máháníámù àti gbogbo Básánì, gbogbo agbégbé ilẹ̀ Ógù ọba Básánì, èyí tí í se ibùgbé Jáírì ní Básánì, ọgọ́ta ìlú,
31 ìdajì Gílíádì, àti Ásítarótù àti Édírérì (àwọn ìlú ọba Ógù ní Básánì). Èyí ni fún irú àwọn ọmọ Mákírì ọmọ Mánásè fún ààbọ̀ àwọn ọmọ Mákírì, ní agbo ilé ní agbo ilé.
32 Èyí ni ogún tí Mósè fi fún wọn nígbà tí ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Móábù ní ìhà kéjì Jọ́dánì ní ìlà-oòrùn Jẹ́ríkò.