5 Àti ilẹ̀ àwọn ara Gíbálì, àti gbogbo àwọn Lẹ́bánónì dé ìlà-oòrùn, láti Baalì-Gádì ní ìṣàlẹ̀ Okè Hámónì dé Lebo-Hámátì.
6 “Ní ti gbogbo àwọn olùgbé agbégbé òkè, láti Lẹ́bánónì sí Mísiréífótì-Máímù, àní, gbogbo àwọn ará Sídónì, èmi fúnra mi ní yóò lé wọn jáde ní iwájú àwọn ará Ísírẹ́lì. Kí o ri dájú pé o pín ilẹ̀ yí fún Ísírẹ́lì ní ilẹ̀ ìní, gẹ́gẹ́ bí mo ṣe fi àṣẹ fún ọ,
7 pín ilẹ̀ yìí ní ilẹ̀-ìní fún àwọn ẹ̀yà mẹ́sàn án àti ìdajì ẹ̀yà Mànásè.”
8 Àwọn ìdajì ẹ̀yà Mánásè tí ó kù, àti àwọn Rúbẹ́nì àti àwọn Gádì ti gba ilẹ̀ ìní, tí Mósè ti fún wọn ní ìhà ìlà-oòrùn Jọ́dánì bí Mósè ìránṣẹ́ Olúwa ti fi fún wọn.
9 Ó sì lọ títí láti Áreórì tí ń bẹ létí Ánónì-Gógì, àti láti ìlú náà tí ń bẹ ní àárin Gógì, àti pẹ̀lú gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀ Médébà títí dé Díbónì.
10 Gbogbo ìlú Síhónì ọba àwọn Ámórì, tí ó ṣe àkóso ní Hésíbónì, títí dé ààlà àwọn ará Ámónì.
11 Àti Gílíádì, ní agbégbé àwọn ènìyàn Gésúrì àti Máákà, gbogbo Okè Hámónì àti gbogbo Básánì títí dé Sálẹ́kà,