6 Nítorí tí àwọn ọmọbìnrin ẹ̀yà Mànásè gba ìní ní àárin àwọn ọmọkùnrin. Ilẹ̀ Gílíádì sì jẹ́ ti ìyókù àwọn ọmọ Mánásè.
7 Agbégbé Mánásè sì fẹ̀ láti Áṣírìu títí dé Míkímẹ́tatì ní ìlà oòrùn Sékémù. Ààlà rẹ̀ sì lọ sí ìhà gúsù títí tó fi dé ibi tí àwọn ènìyàn ń gbé ní Tápúà,
8 (Mánásè lo ni ilẹ̀ Tápúà, ṣùgbọ́n Tápúà fúnra rẹ̀ to wa, ni ààlà ilẹ́ Mánásè jẹ ti àwọn ará Éfúráímù.)
9 Ààlà náà sì tún tẹ̀ṣíwájú lọ sí gúsù dé Kana-Ráfínì. Àwọn ìlú tí ó jẹ́ ti Éfúráímù wà ní àárin àwọn ìlú Mánásè, ṣùgbọ́n ààlà Mánásè ni ìhà àríwá Ráfínì, ó sì pin sí òkun.
10 Ìhà gúsù ilẹ̀ náà jẹ́ ti Éfúráímù, ṣùgbọ́n ìhà àríwá jẹ́ ti Mánásè. Ilẹ̀ Mánásè dé òkun, Ásérì sì jẹ́ ààlà rẹ̀ ní àríwá, nígbà Ísákárì jẹ́ ààlà ti ìlà-oòrùn.
11 Ní àárin Ísákárì àti Ásérì, Mánásè tún ni Bẹti-Ṣánì, Íbílémù àti àwọn ènìyàn Dórì, Énídórì, Táánákì àti Mégídò pẹ̀lú àwọn abúlé tí ó yí wọn ká (ìkẹ́ta nínú orúkọ wọn ní Náfótì).
12 Ṣíbẹ̀, àwọn ọmọ Mánásè kò lè gba àwọn ìlú wọ̀nyí, nítorí àwọn ará Kénánì ti pinnu láti gbé ní ilẹ̀ náà.