23 Ìlú wọ̀nyí àti iletò wọn jẹ́ ìní ẹ̀yà Ísákárì, ní agbo ilé agbo ilé.
24 Gègé karùnún jáde fún ẹ̀yà Áṣíérì, ní agbo ilé agbo ilé.
25 Lára ilẹ̀ wọn ni èyí:Hélíkátì, Hálì, Bẹ́tẹ́nì, Ákísáfù,
26 Álàmélékì, Ámádì, àti Míṣálì. Ní ìhà ìwọ̀-oòrùn ààlà náà dé Kámẹ́lì àti Ṣíhórì-Líbínátì.
27 Nígbà náà ni o yí sí ìhà ilà-oòrùn Bẹti-Dágónì, dé Sébúlúnì àti Àfonífojì Ífíta-Élì, ó sì lọ sí àríwá sí Bẹti-Ẹ́mẹ́kì àti Néíélì, ó sì kọjá lọ sí Kábúlì ní apá òsì.
28 Ó sì lọ sí Ábídónì, Réóbù, Hámónì àti Kánà títí dé Sídónì ńlá.
29 Ààlà náà sì tẹ̀ sí ìhà Rámà, ó sì lọ sí ìlú olódi Tirè, ó sì yà sí Hósà, ó sì jáde ní òkun ní ilẹ̀ Ákísíbì,